Pages

Saturday, May 07, 2016

YORUBA OOO!-"LISA"-IWE Yooba Atata ni Facebook

Yooba Atata's post.
Yooba Atata with Akintola Musibau Ayobami and 35 others.
LISA
Oye ilu ni Lisa, gẹgẹbi Ọtun, Osi, Balogun ati Aṣipa.
Lisa ni awọn akigbe maa nki bayi pe:
Lisa bara ọgọ, arukuoloku ma ṣ'ọfẹ
Agaraolu onida majẹni
Ofinranwale onida majeeyan
Ọkunrin l'ada, ọkunrin l'akọ, ẹni to mu lọwọ paapaa, ọkunrin ni. Dajudaju, akọni ni nj'oye Lisa.
Awọn kan a maa wipe:
Ki Aṣipa to jẹ Oluwo, ọna a jin, bi Lisa ba wa l'aaye, Aṣipa o le r'oye Oluwo jẹ.
Njẹ ẹyin naa ngbọ bẹẹ?
Oye ọdẹ ni Aṣipa. Aṣipa aworo ogun aleṣiwọdo, okunmọlosun-kunmọlata.
Ọkunrin gbọin-gbọin ni Aṣipa naa.
Kini ajọṣepọ pataki to wa l'aarin Lisa ati Aṣipa? Abi oye ọdẹ ni Lisa naa?
Njẹ a le sọ pe Lisa ṣ'agba Aṣipa ninu agbekalẹ oye ilu?
Kini itumọ Lisa, kini iṣẹ Lisa l'aarin ilu?
https://m.facebook.com/yooba.atata?fref=nf&refid=52&__tn__=C

Sent from my BlackBerry wireless device from MTN

No comments:

Post a Comment